Omo Yoruba Atata
Description
Keep Our culture as Yoruba.
Omo Yoruba Atata ni eto lati muwa setigbo gbogbo omo yoruba kari aye,awon; iwe itan,aroso,ewi,oriki ati beebeelo.
Tell your friends
RECENT FACEBOOK POSTS
facebook.comJ.F Odunjo EWÌ ISÉ NI ÒÒGÙN ÌSÉ MÚRA SÍ ISÉ RE, ÒRÉ MI ISÉ NI A FI Í DI ENI GIGA BÍ A KÒ BÁ RÉNI FÈYÌN TÌ, BÍ ÒLE LÀ Á RÍ BÍ A KO RÉNI GBÉKÈLÉ À A TERA MÓ ISÉ ENI ÌYÁ RE LÈ LÓWÓ LÓWÓ BÀBÁ SÌ LÈ LÉSIN LÉÈKÀN BÍ O BÁ GBÓJÚ LÉ WON O TÉ TÁN NI MO SO FÚN O OHUN TÍ A KÒ BA JÌYÀ FÚN KÌ Í LÈ TÓJÓ OHUN TÍ A BÁ FARA SISÉ FÚN NÍ Í PÉ LÓWÓ ENI APÁ LARÁ ÌGÙNPÁ NÌYEKAN BÍ AYÉ N FÉ O LÓNÌÍ BÍ O BÁ LÓWÓ LÓWÓ NI WON Á MÁA FÉ O LÓLA TÀBÍ TÍ O BÁ WÀ NÍ IPÒ ÀTÀTÀ AYÉ Á YÉ O SÍ TÈRÍN-TÈRÍN JÉ KÍ O DI ENI TI N RÁÁGÓ KÍ O RÍ BÁYÉ TI Í YINMÚ SINI ÈKÓ SÌ TÚN N SONI Í DÒGÁ MÚRA KÍ O KÓ O DÁRADÁRA BÍ O SÌ RÍ ÒPÒ ÈNÌYÀN TÍ WÓN N FI ÈKÓ SE ÈRÍN RÍN DÁKUN MÁ SE FARA WÉ WON ÌYÀ N BÒ FÓMO TÍ KÒ GBÓN EKÚN N BE FÓMO TÓ N SÁ KIRI MÁ FÒWÚRÒ SERÉ, ÒRÉ MI Mú RA SÍSÉ, OJÓ N LO #Adekola Adekunle Olamilekan
Ààlọ́ àpagbè(Ìjàpá àti babaláwo) Ní ayé àtijọ́, Yánníbo ìyàwó Ìjàpá kò fi inú ṣe oyún, kò fẹ̀yìn gbọ́'mọ pọ̀n. Ìjàpá ńgbìyànjú bí ìyàwó òun yóò ṣe lóyún tí yóò sì bímọ. Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí ilé olóògùn kiri. Ó ní ìgbàgbọ́ pé àwọn olóògùn lè tán ìṣòro ìyàwó òun. Nígbà tí ó ṣe, ó gbúròó babaláwo kan pé ó gbóná, ògbólógbòó awo ni baba yìí ṣe. Ìjàpá gba ọ̀dọ̀ babaláwo yìí lọ, ó dé bẹ̀, ó kó, ó rò. Ó sọ b'isu ṣe kú bí ọ̀bẹ ṣe bẹ́ fún babaláwo náà. Babaláwo gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ sánlẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ki Ifá. Nígbà tí ó ṣe, ó sọ fún Ìjàpá pé ìyàwó rẹ̀ yóò bímọ. Babaláwo sọ fún Ìjàpá pé òun yóò ṣe àsèjẹ kan fún un tí yóò lọ gbé fún ìyàwó rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún Ìjàpá pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí àsèjẹ náà kan òun l'ẹ́nu. Babaláwo ṣe àsèjẹ, ó gbé fún Ìjàpá kí ó lọ gbé e fún ìyàwó rẹ̀ nílé. Olè àti ọ̀kànjúà ni Ìjàpá bí ó ti gbọ́ òórùn àsèjẹ tí ó ń ta ṣánṣán, ni ó bá tọ́ àsèjẹ lá, ó rò nínú ara rẹ̀ pé kékeré tí òun tọ́lá kò le ṣe òun ní nǹkankan. Ṣùgbọ́n kínni a ó rìí, inú Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú, inú rẹ̀ ń yọ bí obìnrin tí ó lóyún. Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí ba Ìjàpá ni ó bá gba ilé babaláwo lọ. Bí ó ṣe ilé babaláwo ni ó bẹ̀rẹ̀ sí kọrin báyìí pé : Lílé : Bàba - láwo mo wá bẹ̀bẹ̀ Ègbè : Alugbinrin Lílé : Ògùngùn tó ṣe fún mi lẹ́ẹ̀kàn Ègbè : Alugbinrin Lílé : Ó ní n mọ́ mọ̀ mọ́wọ́ banu Ègbè : Alugbinrin Lílé : Ó ní n mọ́ mọ̀ mẹ́sẹ̀ banu Ègbè : Alugbinrin Lílé : Gbòǹgbò ọ̀nà ló sì yọ̀ mí tẹ̀rẹ̀rẹ̀ Ègbè : Alugbinrin Lílé : Mo mọ́wọ́ balẹ̀ mó mú banu Ègbè : Alugbinrin Lílé : Mo mẹ́sẹ̀ balẹ̀ mó mú banu Ègbè : Alugbinrin Lílé : Mo bojúwokùn ó rí gbẹndu Ègbè : Alugbinrin Lílé : Babaláwo mo wá bẹ̀bẹ̀ Ègbè : Alugbinrin Àánú Ìjàpá ṣe babaláwo, ó sì pinnu láti dárí ìwà ọ̀kànjúà àti olè tí ó hù jìn-ín, babaláwo fún Ìjàpá ní àsèjẹ mìíràn, èyí tí ó mú inú rẹ̀ tí ó yọ bọmbọ rẹlẹ̀. Lẹ́hìn náà ni babaláwo ṣe àsèjẹ mìíràn fún ìyàwó Ìjàpá. Ṣùgbọ́n Ìjàpá tún jí àsèjẹ ìyàwó rẹ̀ jẹ. Bákan náà, inú Ìjàpá tún bẹ̀rẹ̀ sí wú bí ti olóyún. Ẹ̀rù tún ba Ìjàpá ó tún padà sí ọ̀dọ̀ babaláwo pẹ̀lú orin tí ó kọ ní àkọ́kọ́ : Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé ohun tí Ìjàpá ṣe kò dùn mọ́ babaláwo nínú ó gbà láti ràn-án lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kejì. Babaláwo tún ṣe àsèjẹ mìíràn fún Ìjàpá tí inú rẹ̀ fi tún rẹlẹ̀. Babaláwo tún wá ṣe àsèjẹ lẹ́ẹ̀kẹta fún Ìjàpá pé kí ó gbé fún Yánníbo ìyàwó rẹ̀. Ṣùgbọ́n ìwà kìí fi oníwà sílẹ̀,ọ̀kànjúà ojú Ìjàpá kò fi sílẹ̀, bí ó ti ń gbọ́ òórùn àsèjẹ ni ọkàn rẹ̀ tún ń dá tuntun. Ìjàpá tún tọ́ àsèjẹ wò, lọ́gán ni inú rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wú bí ẹni pé ó lóyún. Ìjàpá aláìní ìtìjú tún padà sí ọ̀dọ̀ babaláwo. Ṣùgbọ́n ní ẹ̀ẹ̀kan yìí ẹ̀pa kò bóró mọ́. Òkété ti bórù mọ́ Ìjàpá lọ́wọ́. Babaláwo kọ̀ jálẹ̀ láti tún ran Ìjàpá lọ́wọ́. Inú Ìjàpá sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wú títí ó fi bẹ́. Báyìí ni Ìjàpá fi ojú kòkòrò àti ọ̀kànjúà pa ara rẹ̀. Ẹ̀yin ará wa, ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́?
Oríkì òmù àrán láti ẹnu ajóbíewé
OBÌNRIN KAN ÀTI ÀWỌN ỌMỌ RẸ MẸ̀TA Ní ìlú kan orúkọ ìlú náà ni Olówó obìnrin kan wà tí ó bí ọmọ mẹ́ta. Orúkọ àwọn ọmọ náà nìwọ̀nyí ;wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ làá sẹ́gi, wàràwàrà làá wọ̀gbẹ́ àti ọmọniyùn tí ó jẹ́ ọmọ ìkẹyìn wọn léńjéléńjé. Obìnrin yìí wá fẹ́ràn Ọmọniyùn ju àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ, kò sì fi ìfẹ́ yìí pamọ́ fún àwọn ẹ̀gbọ́n Ọmọniyùn. Nígbà tí ó di ọjọ́ kan, àwọn ọmọ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jáde nílé, wọn kò sì mọ ọ̀nà ilé mọ́. Obìnrin yìí wá àwọn ọmọ rẹ̀ títí kò rí wọn. Nígbà tí ó ṣe, obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú orin àti omijé lójú. Obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin báyìí pé : Lílé : Èrò ọjà olówó Ègbè : jàlòlòjalóló Lílé : Taa ló bá mi rọ́mọ mi? Ègbè : jàlòlòjalóló Lílé : Kíni orúkọ t'ọ́mọ rẹ máa ń jẹ́? Ègbè : jàlòlòjalóló Lílé : Ọkan wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ làń sẹ́gi Ègbè : jàlòlòjalóló Lílé : Ọkan wàràwàrà làń wọ̀gbẹ́ Ègbè: jàlòlòjalóló Lílé : Okan Ọmọniyùn kékeré, Ọ̀rọ ọmọniyùn ló dùn mí jọjọ Ègbè : jàlòlòjalóló L Lílé : Èrò ọjà olówó Ègbè : jàlòlòjalóló Lílé : Èrò ọjà ọ́lọ́mọ Ègbè : jàlòlòjalóló Bí ó ṣe ń kọ orin yìí, Ọbìnrin yìí kò mọ̀ pé wọ́n ti gbé àwọn ọmọ òun pamọ́. Àwọn tí wọ́n gbé àwọn ọmọ yìí pamọ́ fẹ́ fi dá obìnrin yìí lára wípé kò yẹ kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju èkejì lọ nítorí Olódùmarè ló fi àwọn ọmọ yìí ta wá lọ́rẹ. Obìnrin yìí tún bẹ̀rẹ̀ orin bí ti ìṣáájú. Nígbà tí ó ṣe, wọ́n taari méjì nínú àwọn ọmọ obìnrin yìí síta. Inú obìnrin yìí kò dùn torí pé kò rí ọmọniyùn tííse àbíkẹ́yìn ọmọ rẹ̀. Àwọn ènìyàn sì gbìmọ̀ pọ̀ láti dá obìnrin yìí lójú. Ohun tí wọ́n ṣe ni pé wọ́n gé orí Ọmọniyùn, wọ́n sọ sí obìnrin yìí. Bí obìnrin yìí ti ríi ni ó bú sí ẹkún ni ó tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin. Kò pẹ́ ni wọ́n ju òkùtù Ọmọniyùn sí ìyá rẹ̀. Inú ìyá ọmọniyùn bàjé gidig, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún lọ sí ilé. Ìdí àlọ́ yìí ni pé kò yẹ kí á máa fẹ́ràn ọmọ kan ju ọmọ kejì lọ torí a kò mọ irú ohun tí àwọn ọmọ yìí yóò dà ní ọjọ́ ọ̀la. Òkúta tí ọ̀mọ̀lé kọ̀ tún lè padà wá di pàtàkì igun ilé ní ọjọ́ ọ̀la.
Oríkì ÌLORIN Ìlorin àfọ̀njá ẹnu dùn juyò Ìlú tí wọ́n ti ń di gàárì gesin ń kẹ́sẹ́ Omo a tàpín onîpín ràpín A t'ọmọ ọlọ́mọ fi bọ́ tiwọn A t'ọ̀tọ̀tọ̀ èèyàn fi rokùn idà Wọn ò s'ẹbọ wọn ò s'òògùn Ìlú tóbi tó báyìí kò léégún Kéhú ni wọ́n ń ké lóde Ìlorin Ẹṣin leégún wọn nílé oláderin Ọkọ̀ sì tọrọ ibẹ̀ Ají fi káláàmù dá'mọ lẹ́kun àríse kọ́ńdú kọ́ńdú Omo ají polówó Kéhú tantantan Àwa ò nílù l'agbaajì Kéhú ni wọ́n ń ké nílé baba tóbí wa lọ́mọ Ìyekan ìwà ni foni foda laso esu mọ Baba yín lo sọ kinira dòfo Èyin lẹ sọ fààfà dilẹ̀ Ogun l'Àfọ̀njá lọ tí ò padà wálé mọ́ Nkó kì yín oníwà Abídiire L'ẹ́ja n lápó L'ẹ́ja n lọ́run Lẹ dágbọ̀n ìsàlè wọdò Ajagasẹ̀ Ìlorin bèèrè kí o tó wọ̀ọ́ Kí o má baà kó gijogijo Nílé ọmọ ọláderin Ọmọ afọ̀kọ̀jà A fidà pa tẹngbẹ.
IJESHA Ijesa lobiri omo owa lokun Owa omo a teni gbogun Ijesa modo a pana da Ijesa o sun ore a tin leni owa Ogun to ja jesa lora eni atin tan Ogun toja boriola nlo keni ewele lo Ijesa lobiri omo olobi kunduru Omo olobi wo n wo nti wo Ijesa lomo olobi wowo nti wo Eyi toba feni a wo sinu ile Eyi ti koba feni a wo siju eranko Eranko a fi sonje je Ijesa omo olobi ni kola Dagba bi erin wo meji awere Ijesa omo o dami nu doju igba de Ogun ijesa ti ko ni mo laya mo le duro Nibi to gbe duro lomo owa ti nya ba o Bi ti nyaba po jumi Beeni nyaba pesan pewa O yaba kere nibi ti ngbe ndigun O ya bokan rada rada Ti nuse lodo lomo owa mu wale Olobiri omo oloku egbe Ijesa lobiri omo oloku imamaran. Awon eniti ko gbon Awon eniti ko meyin oran Nwon a lokan soso ijesa bi tuuku wolu Igba won bi erin jako abia abia esi Sugbon nigbati emi gbon Ti emi si meyin oran Mo ni okan soso ijesa Bi olokiki wolu Igba won bi wundia (olomoge) wonu oko Ijesa to tekiti bo fun ni lobi meji Oye ka dupe gidigidi lowo re Oke ohun koya gun boro Oke ohun koya gun kankan Ni won nki olobiri Owa bokun Owa omo a teni gbokun Ijesa modo apanada Ijesa lobiri ara ode ido Ijesa abe togunra lu omo erin losin Okekeke j'aso igbajo Egodo ti emi laso ijesa Eyo wero aremu asansi bara idi A ma bawon joloye A ki joloye dunran ijesa A ki joloye dun yin Owa lokun,Owa omo atenigbokun Ijesa ma na mi,okoye lo lokiti Ijesa o ridi isana Nile lomo owa ti fon na roko Olobiri ibi tagbe mole koto jabute Ibi ta gbemu semi enu ibe lo mo Ibi agbe madido gbogofa eniyan Nibi tagbe meru owa Kotun hu gbe mo lailai Akata kiti a mu leya meji awere Ijesa omo o dami nu doju igba de Owa omo a teni gbokun Ijesa modo apanada Ogun toja jesa lorun eni atintan Ogun to jale Owa lo keni ewele lo Pakiti ki seni ijesa Pakiti ki seni iran re A ki ki jesa ka ma jobi togbo Olobiri jowo fun mi lobi to megbe Ki n rohun muje. ORIN IJESHA 1) Omo e bami joloye,oloye la njo. 2) A ki bani rin ka ma mole eni, ijesa nile A ki bani rin ka ma mole eni, ekiti nile 3) Beru nba yin ewi o, eru o bomo Owa o 4) Omo jesa dun bio, boo bi loni a rin lola a benu kolobo. 5) Iya n ma re'ja o, boya ma romoge togbo ke, n ma re'ja mo alawona ni e pe funmi, omo ijesa ni e pe funmi. 6) Mo roye henhen.
(Ewì) ISÉ Lògùn ìsé Ise Logun ise Mura si se re, ore mi Ise la fi ndeni giga Bi a ko ba reni fehin ti Bi ole la ri Bi a ko ba reni gbekele A te ra mo se ni Iya re le lowo lowo Baba re le lesin lêkàn Ti o ba gbojule wón O te tan ni mo so fún o Apa lara igupa ni ye kan B'aiye ba fe o loni Ti o ba lowo lowo, won a tun fe o lola Abi ko wa nipo atata Aiye a ye o si terin terin Je ki o deni ti ra ngó Ko ri bi won ti nyin mu si o Iya mbe fomo ti ko gbon Ekún mbe fomo ti nsare kiri Mafowuro sere ore mi Mura sise ojo nlo.
Sàfiwé ìtumò àwon àmìnwòrán yìí ní òwe yorùbá? 1. 👁🦀👦🏽 2. 🏃🏾🚷🏠 3. 👑🔟🌄🔟 4. 🌴⬆☹ 5. 💬🐎🗣 6. 💵🚲🙌🏾 7. 👁1⃣🔪 8. 🐞💃🏽🐓❌ 9. 🙏🏾🗡🕌⛪ 10. ✋👶🌴✋👴🍶 Eni bá láyà!
OMO ALÁIGBORÀN Ní ayé àtijó, ìdílé kan wà, oko, aya àti omo won okùnrin. Nïgbà tí omo t'oko ti'yàwó yìí dàgbà, ó so fún àwon òbí rè pé isé ode ni òun yóò se. Àwon òbí rè kò fé kí ó máa de igbó kiri, ni wón bá wá eran sílè pé kí o fi máa kó isé ode. Sùgbón omo yìí kò jálè pé òun kò ní se ode nínú ilé áfi tí òun bá lo sí inú igbó tí Ekùn àti Èrin wà. Wón wí fún omo yìí kò gbó. Nígbà tí wón rí wí pé omo yìí kò gbó ni wón bá fi sílè. Àwon òbí rè ra ìbon àti àwon nnkan tí yóò máa fi s'ode fún-un. Bí omo yìí se gba inú igbó lo nìyí. Kò pé tí ó wo inú igbó, ni òjò ńlá kan bèrè. Òjò yìí pò púpò débi pé ó férè wú òkú òle. Níbi tí omo yìí fara pamó sí ni àgbàrá òjò ti bèrè sí wó omo yìí lo. Àgbàrá òjò gbé omo yìí títí ó fi dé inú òfin. Ní inú òfin ni alábahun, Ijàpátìrókò oko yánníbo ti rí omokùnrin yìí tí ó sì múu lo sí ilé rè. Nígbà tí Ijàpá mú omo yìí délé, ó fi pamó sí inú ìlù rè. Ní Ijàpá bá ti ń lo s'ode ni yóò gbé ìlù yìí lówó. Bí ó bá ti dé òde àríyá ni yóò so báyìí : "Àyàn dúndúnún Àyàn dùndundùn, Àyàn fo'hùn enu rè kí n gbó "béè ni Ijàpá yóò lu omokùnrin tí ó wà nínú ìlù ní kòngó lórí. Yóò so pé Àyàn dúndúnún Àyàn dùndundùn, Àyàn fo'hùn enu rè kí n gbó. Bí ó bá ti se báyìí ni omodékùnrin yìí nâ yóò bèrè sí ko'rin báyìí pé : Lílé : Réréo réré omo Olúwo Ègbè: Ààgbááyùnrééré Lílé : Réréo réré omo Olúwo Ègbè : Ààgbááyùnrééré Lílé : Bàbá f'eran sílè ó ní kí ń kóde se Ègbè : Ààgbááyùnrééré Lílé : Iyá f'eran sílè ó ní kí ń kóde se Ègbè : Ààgbááyùnrééré Lílé : MO l'ódigbó efàn,ó d'i- gbó erin Ègbè : Ààgbááyùnrééré Lílé : Àgbàrá òjò ló gbémi dófìn mo d'erú ahun Ègbè : Ààgbáyùnréré Lílé : Réréo réré òmó Ólúwo Ègbè : Ààgbáyùnréré Bí omo yìí ti ń ko'rin ni gbogbo àwon ènìyàn bèrè sí 'jó tí agbo àríyá náà ń so sùsù. Báyìí ni Ijàpá ń se tí ó sì só di olókìkí onílù láàrin ìlú Nígbà tí ó di ojó kan, orí omodékùnrin náà gbé aláwoore kòó. Àwon ènìyàn ti mò wí pé ènìyàn ni Ijàpá kì sínú ìlù rè ti ń ko'rin fún gbogbo ayé. Wón sì pinnu láti mo ohun tí ń ko'rin nínú ìlù Ijàpá. Ijàpá lo sí òde àríyá ní ojó kan, bí ó ti s' eré tán ni àwon ènìyàn fún-un ní oúnje wón sì tún fún-un ní emu mu. Gbogbo wa ni a mò pé olójúkòkòrò ni Ijàpá, ó jeun, ó sì tún mu emu lée lórí. Ijàpá mu emu lópòlopò, èyí tí ó jé kí ó sùn lo fonfon. Bí ó ti sùn lo dáadáa ni àwon ènìyàn la ìlù Ijàpá tí wón yo omodékùnrin jáde. Enu ya àwon ènìyàn láti ríi pé omo ènìyàn ni Ijàpá kì sínú ìlù. Bí wón se yo omodékùnrin yìí kúrò ni wón ki òpòló sí inú ìlù náà tí wón sì tún rán-an padà. Nígbà tí Ijàpá jí láti ojú oorun, ó tún fé bèrè eré síse. Bí ó ti wí bí ó ti máa ń wí ni òpòló bèrè sí dún nínú ìlù rè. Ojú ti Ijàpá lópòlopò, wón sì bèrè sí fi se eléyà. Idí ÀLÓ yìí ni pé, kò ye kí á máa ta àwon òbí wa lénu. Àìgboràn omodékùnrin yìí ló kó ìyà jéé láti owó Ijàpá.